Oniruuru awọn ẹgbẹ ti wọn wa lẹyin odi ti gboṣuba fun Gomina Ademọla Adeleke lori awọn atunto oriṣiriṣi to mu ba ọrọ iwakusa nipinlẹ Ọṣun.
Gbogbo wọn ni wọn sọ pe awọn igbesẹ ti ko ṣẹlẹ ri, eleyii to si wu eeyan lori ni gomina n gbe lori ẹka naa.
Gomina Ademọla, ẹni to n pada bọ wa si orileede Naijiria lẹyin irinajo rẹ si iha Ariwa ilẹ Faranse nibi to ti kopa ninu apero lori awọn nnkan ọsin-abiyẹ lo ṣepade pẹlu awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun niluu London, nibẹ lo si ti salaye oniruuru igbesẹ to n gbe lẹkajẹka lati sọ ipinlẹ Ọṣun di apewaawo kaakiri agbaye.
Ọkan lara awọn ẹgbẹ naa ti wọn pe ni Osun UK Professionals eleyii ti Bimbọ Adekẹmi ko sodi, sọ pe iyalẹnu lo jẹ bi gomina ṣe n ṣe awọn iṣe idagbasoke agbayamuyamu nipinlẹ Ọṣun lasiko yii ti eto ọrọ-aje le koko lorileede Naijiria.
Ẹgbẹ naa sọ pe awọn iṣẹ akanṣe jẹ ọpakutẹlẹ si imugbooro eto ọrọ aje labẹnu nipasẹ eyi ti yoo si rọrun fun awọn olokoowo lati waa daṣẹ silẹ nipinlẹ Ọṣun.
Ẹgbẹ yii gboṣuba fun igboya ti Gomina Adeleke ni lati beere ẹtọ ipinlẹ Ọṣun lọwọ awọn ileeṣẹ iwakusa ti wọn wa l'Ọṣun, wọn ni igbesẹ akin, to si ṣafihan gomina bii adari to ṣe e mu yangan ni pẹlu ohun to n ṣẹlẹ lọwọ lori ileeṣẹ Thors Explorations Limited.
Gẹgẹ bi Adekẹmi ṣe wi, “A ri igbesẹ ti gomina gbe lori ileeṣe iwakusa Thors Explorations gẹgẹ bii eyi to tọ. Nigba to jẹ pe ṣe lawọn miran maa n beere fun sisan iru owo bẹẹ nibọbẹ, ṣe ni Gomina Adeleke n wa ọna ti wọn yoo fi san owo ọhun sinu asunwọn ijọba.
''Igba akọkọ niyii ti a maa ri gomina kan ti ko beere owo lọwọ awọn ileeṣẹ iwakusa sapo araa rẹ, ṣugbọn to n beere ohun to jẹ ẹtọ nilana ofin fun ipinlẹ rẹ.
“A gboṣuba fun igboya gomina lori igbesẹ rẹ lati mu ki eto ọrọ-aje rugọgọ sii. Ẹ maṣe kaarẹ ninu awọn oniruuru eto lati ṣagbekalẹ ijọba to duroore fawọn araalu. Pupọ ninu wa la n bojuwẹyin, ti a si n ni i lọkan lati wa daṣẹ silẹ nile.”
Awọn ẹgbẹ miran, Osun UK Royal Group ti Timilẹyin Oluyẹmi Ajayi, ọmọbibi ilẹ Ijeṣa, jẹ adari fun ṣalaye pe Gomina Adeleke ti tun ireti ọpọ awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ti wọn n gbe loke-okun ṣe nipasẹ awọn eto rẹ ni ẹka ọrọ-aje, ilera, ẹkọ, iṣẹ agbẹ, ayipada oju ọjọ atawọn iṣẹ akanṣe.
“Ọlọla julọ, a gboriyin fun afojusun rere ti ẹ ni si iṣejọba, a ti ri i ka, bẹẹ ni awọn akẹẹgbẹ wa ti wọn lọ sile n mu iroyin rere wa fun wa, inu wa dun lati pe ara wa ni ọmọbibi ipinlẹ Ọṣun.
“Ẹ n ṣe daadaa ninu imọ ẹrọ, ironilagbara, alajẹṣẹku, ẹ n san ọpọlọpọ biliọnu owo awọn oṣiṣẹfẹyinti, ati gbese owo-oṣu. Awọn oṣiṣẹ ijọba n gbadun ijọba yin, o si n ya awọn eeyan lẹnu pe laarin ọdun meji pere lawọn nnkan yii n ṣẹlẹ. Gbogbo wa la maa wale lati forukọsilẹ fun idibo ọdun 2026.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Adeleke sọ pe inu oun dun fun awọn nnkan ti oun n gbọ latẹnu awọn ara ilẹ okeere, o si ṣeleri pe iṣejọba oun ko nii dawọ iṣẹ rere duro.
O ke si awọn eeyan naa lati ṣiṣẹ pẹlu ijọba lati jẹ ki gbogbo agbaye ri ohun rere nipa Ọṣun, ki wọn waa daṣẹ silẹ nile, nitori ijọba oun ni afojusun lati tete mu idagbasoke ba gbogbo ẹka nipinlẹ Ọṣun.
No comments:
Post a Comment