Kọmiṣanna tẹlẹ fun eto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Sunday Akere, ti sọ pe ko si wahala kankan laarin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ati Alhaji Gboyega Oyetọla, ṣugbọn ṣe ni Arẹgbẹṣọla kan n fi Oyetọla boju lati ba Aarẹ Bọla Tinubu ja.
Nibi ifọrọwerọ ti League of Veteran Journalists nipinlẹ Ọṣun ṣagbekalẹ rẹ ni Akere ti sọrọ yii.
Akere ṣalaye pe 'Arẹgbẹṣọla yan ọpọlọpọ awọn abẹṣinkawọ silẹ fun Oyetọla ko too gbe ijọba silẹ fun un, nigba to di pe ọrọ yii n da aawọ silẹ, bii ẹẹmẹrin ni Oloye Bisi Akande pe wọn sipade lati ba wọn pari aawọ naa, nibi eyi to gbẹyin, Arẹgbẹṣọla lo ṣe akọsilẹ gbogbo nnkan ti wọn sọ.
''Wọn fẹnuko pe ki wọn fi ọrọ iṣejọba silẹ fun Oyetọla, ki wọn faaye gba Oyetọla lati di gomina lẹẹkeji, bẹẹ ni wọn ni ki ọrọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC di ti Baba Akande, Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla.
''Nigba ti a bẹrẹ iforukọsilẹ ẹgbẹ lasiko korona, Oyetọla pe Arẹgbẹṣọla lati beere igba ti yoo wale fun iforukọsilẹ tirẹ, ki gbogbo wa le tẹle e lọ.
''Ṣugbọn o ya wa lẹnu nigba ti a ri fidio ibi ti Arẹgbẹṣọla ti lọọ forukọsilẹ niluu Ileṣa, to si bẹrẹ si i bu Aarẹ Tinubu, nibẹ la ti mọ pe ṣe lo n fi Oyetọla boju lati ba Tinubu ja.
'O han gbangba pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn n ṣiṣẹ fun. A si ti kọwe si awọn adari wa lapapọ l'Abuja lori oniruuru iwa ti wọn n hu, paapaa, lori ọrọ Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla nitori a ko lagbara nipinlẹ lati ṣe ohunkohun lorii rẹ''
No comments:
Post a Comment