IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 17 October 2024

Adeleke gboṣuba fun Ọọni Ogunwusi layajọ aadọta ọdun loke-eepẹ


Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ba Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, dawọọdunnu ayajọ aadọta ọdun to dele aye. 


Adeleke ṣapejuwe Ọba Ogunwusi gẹgẹ bii aṣaaju to ṣe e tẹlẹ, o ni ipa ti Arole Oduduwa n ko lati jẹ ki alaafia jọba lagbegbe rẹ ati kaakiri ilẹ Yoruba fi i han gẹgẹ bii ẹni to lafojusun rere fun idagbasoke awọn eeyan rẹ. 


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Rasheed Ọlawale, fi sita lo ti gboriyin fun Ọọni lori oniruuru igbesẹ to n gbe lati mu igbelarugẹ ba aṣa ilẹ Yoruba. 


O ni kabiesi naa jẹ afara to ti mu ki ọpọ idagbasoke de ba ilu rẹ pẹlu ajọ awọn lọbalọba nipinlẹ Ọṣun ati kaakiri orileede yii. 


Atẹjade naa ni "Inu mi dun lati ba kabiesi Arole Oduduwa, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ẹnitan, Ojaja II, Ọọni Ifẹ, yọ ayọ ayajọ aadọta ọdun ti wọn de ile aye. Ọjọọbi yii ṣafihan oore-ọfẹ lọpọlọpọ ati aye to kun fun ifaraẹnijin fun iran ọmọniyan. 


"Ipa ti Ọba Ogunwusi n ko gẹgẹ bii ẹni to wa nigbọnnu ogun-ini iran yii jẹ eyi ti a mọriri rẹ pupọ. Mo gboriyin fun bi kabiesi ṣe n ṣe igbelarugẹ iran Yoruba nile ati lẹyin odi, eleyii to ti sọ wa di iran ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lagbaye''


Gomina Adeleke waa gbadura pe ki Eledumare tubọ maa fun kabiesi ni ilera pipe ati ọgbọn lati tubọ maa ṣakoso aṣa ati lati maa ko ipa to jọju ninu idagbasoke ipinlẹ Ọṣun ati orileede yii lapapọ.

No comments:

Post a Comment