Awọn idile ọlọmọọba niluu Itaakun Ikire nijọba ibilẹ Irewọle nipinlẹ Ọṣun ti ke si Gomina Ademọla Adeleke lati kilọ fun awọn oṣiṣẹ kan nileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lati maṣe da wahala silẹ niluu naa.
Ọmọọba Adeoye Dairo to sọrọ lorukọ awọn ọlọmọọba naa, ṣalaye pe ṣe lawọn oṣiṣẹ naa n kọwọ bọ ọrọ Sooko ilu Itaakun lọna to gba lodi si ofin oye jijẹ nibẹ.
Adeoye ṣalaye pe, lai fi ti aṣẹ ile ẹjọ ṣe, awọn oṣiṣẹ naa gbe alakalẹ oye kan, Chieftaincy Declaration, kan jade ninu eyi ti wọn fi idile meji ti wọn jẹ ajeji kun ara ile to n jẹ ọba niluu naa.
O ni idile mẹrin lo wa ninu alakalẹ oye jijẹ ilu naa lati ọdun 1958, iyalẹnu lo si jẹ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa gba ọna makaruuru gbe ohun ti ko si ninu alakalẹ naa jade.
Gẹgẹ bo ṣe wi, "A n ke si Gomina Ademọla Adeleke lati kilọ fun awọn oṣiṣẹ ti wọn n huwa ibajẹ nileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lati dẹkun aṣilo agbara yii. Ọrọ oye ati ọba jijẹ nilẹ Yoruba ki i ṣe ọrọ ẹni to ba lowo ju.
"Ile ọlọmọọba mẹrin to wa niluu Itaakun ni ile Metiku, Falade, Ademuyiwa ati Atẹrẹ ti wọn jẹ ọmọ Awodeyi.
"Bi wọn ṣe deede fi ile Ọmọmimi kun ile ọlọmọọba da wahala silẹ, idi si niyẹn ti wọn fi gbe igbimọ iwadii ti wọn pe ni Abegunde’s Commission of Inquiry, eleyii ti Dokita L.O. Adegbitẹ jẹ alaga rẹ nigba naa.
''Lẹyin ti igbimọ gbe abọ iwadi jade, ijọba ipinlẹ Ọṣun fọwọ si i. Nibẹ ni wọn ti sọ pe ile ọlọmọọba Ademuyiwa, Falade, Metiku ati Atẹrẹ lo wa ni Itaakun. Wọn ni ile Ọmọmimi jinna si ile ọlọmọọba, bẹẹ ni ile Mọlaja ko si lara idile to le jọba nibẹ.
''Iyalẹnu lo waa jẹ bi ile Mọmimi ati Mọlaja ṣe deede di ile ọlọmọọba lai fi ti aṣẹ ile ẹjọ ṣe. Idi niyii ti a fi n ke gbajare si ijọba Ọṣun lati tete da si ọrọ naa, ki awọn oṣiṣẹ rẹ ma baa da wahala silẹ niluu naa.
No comments:
Post a Comment