Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu to wa lorileede yii, Inter-Party Advisory Council (IPAC), ti sọ pe gbọn-in-gbọn-in lawọn wa lẹyin ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, Osun State Independent Electoral Commission (OSIEC) lori eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọdun 2025.
Nibi ipade kan ti awọn ẹgbẹ oṣelu naa ṣe pẹlu alaga ajọ OSIEC, Amofin Hashim Abioye, atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, ni sekiteriati ajọ naa to wa l'Oṣogbo, ni wọn ti sọ pe awọn nigbagbọ kikun ninu ajọ OSIEC.
Gẹgẹ bi alaga wọn, Pasitọ Victor Akande, ṣe ṣalaye, pẹlu oniruuru igbesẹ ti ajọ OSIEC n gbe lati oṣu kin-in-ni ọdun yii ti wọn ti kede pe eto idibo ijọba ibilẹ yoo waye loṣu keji ọdun 2025, awọn mọ pe didun lọsan yoo so.
Akande sọ siwaju pe Amofin Abioye to jẹ alaga OSIEC ti fi ara rẹ han gẹgẹ bii ẹni to ni etiigbọ, to si ni akoyawọ ninu gbogbo nnkan to n ṣe, nitori naa, ko si idi kankan ti ẹnikẹni fi le ṣiyemeji lori rẹ.
Ninu ipade naa, ajọ OSIEC ati IPAC jọ fẹnuko pe ko gbọdọ si ẹgbẹ oṣelu ti yoo maa sọko ọrọ si ẹgbẹ oṣelu miran lasiko ipolongo ibo.
Bakan naa ni wọn ke si ijọba apapọ labẹ Aarẹ Bọla Tinubu lati maṣe gbẹsẹ le owo to jẹ ti awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, eto lori idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ loṣu kin-in-ni ṣaaju idajọ ile ẹjọ to ga julọ lorileede yii to waye loṣu keje lori ominira awọn ijọba ibilẹ.
Ninu ọrọ tirẹ, Amofin Abioye, ṣalaye pe, ohun ti ko ṣẹlẹ ri nipinlẹ Ọṣun lo n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii pẹlu bi ifọwọsowọpọ ṣe wa laarin awọn ẹgbẹ oṣelu ati ajọ OSIEC.
O ni ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun lo wa nibi ipade naa, ninu eyi ti a ti ri ẹgbẹ APC, PDP, NNPP, Accord Party, Boot Party, Labour Party, ZLP, AA, ADP ati bẹẹ bẹẹ lọ.
No comments:
Post a Comment