IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 September 2024

Ọwọ ti tẹ Taju o, faanu mọṣalaaṣi lo ji tu l'Oṣogbo


Ọwọ ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Tajudeen Rilwan, lori ẹsun ole jija. 


Mọṣalaasi kan lagbegbe Omigade niluu Oṣogbo la gbọ pe Taju ti lọọ jale lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan-an ọdun yii. 


Gẹgẹ bi alakoso ajọ naa, Dokita Ọmọyẹle Isaac Adekunle, ṣe ṣalaye, aipẹ yii ni Tajudeen de lati ọgba ẹwọn lori ẹsun ole jija yii kannaa. 


O ni nigba ti ọmọkunrin naa n jẹwọ lo sọ pe ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi nikan loun ti maa n pitu ọwọ oun. 


O ki oun ti figba kan ri ji ẹnijinni ti wọn n lo ni Mọṣalaasi Olokuta lagbegbe Ọja-Ọba niluu Oṣogbo ko too di pe oun waa tu faanu mọsalaaṣi Omigade yii. 


Bakan naa lọwọ tẹ Olatinwọ Quyum ẹni ọdun mọkandinlogun lori ẹsun pe o ji ọkada kan niluu Apomu nipinlẹ Ọṣun. 


Nibi ti Ilesanmi Ọladele to ni ọkada nas gbe e si la gbọ pe Quyum ti ji i, ilu Ifọ nipinlẹ Ogun lo si morile nibi to ti ta a. 


Lẹyin ọpọlọpọ iwadii ni ọwọ tẹ ẹ lọgbọnjọ oṣu kẹjọ ọdun yii to si jẹwọ pe loootọ loun huwa naa.

1 comment: