IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 19 September 2024

Ọwọ ti tẹ Daniel ati Tunji o, eegun ati omi ti wọn fi wẹ oku ni wọn n ta fawọn babalawo n'Ipetu-Ijeṣa


Ọjọ ti pẹ ti awọn ọkunrin meji ti wọn n ṣiṣẹ nile igbokupamọsi kan niluu Ipetu Ijeṣa ti n huwa laabi wọn, ṣugbọn ọwọ palaba wọn ti segi bayii. 

Nigba ti adele alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, ASP Emmanuel Giwa, n ṣalaye nipa iṣẹlẹ naa, o ni egungun awọn oku ti wọn ba gbe sọdọ awọn afurasi naa ni wọn maa n yọ, ti wọn a si ta wọn fun awọn babalawo. 

Awọn afurasi ọhun ni Johnson Daniel, ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Adetunji Okunade, ẹni ọdun mejilelogoji. 

Bakan naa ni wọn maa n gbe omi ti wọn ba fi wẹ oku pamọ sibikan fun awọn babalawo onibara wọn yii fun oniruuru oogun ti awọn yẹn n lo o fun. 

Nigba ti ọwọ tẹ awọn mejeeji yii ni wọn mu awọn ọlọpaa lọ sọdọ Ọlaniyan Azeez, Balogun Temitọpẹ Asimiyu ati Ọladapọ Hammed, Kazeem Rasaq ati Asaka Raufu ti wọn jẹ babalawo. 

Ninu ile Raufu ati Ọladapọ ni wọn ti ba eegun agbari eeyan, nigba ti wọn ba awọtẹlẹ obinrin ati iwe akọsilẹ oogun ninu ile Balogun. 

Emmanuel Giwa sọ siwaju pe awọn afurasi naa ti foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment