IROYIN YAJOYAJO

Friday, 20 September 2024

Ọrọ o tọ si yin lẹnu rara, awin lẹ ṣaa ra fọọmu fawọn oludije yin - OSIEC sọko ọrọ sẹgbẹ APC


Ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ l'Ọṣun ti sọ pe o yẹ ẹni gbogbo ko dinwo alagbafọ, bii ti atọọle kọ, o ni eebu ajọ naa ko si lẹnu ẹgbẹ oselu APC ipinlẹ Ọṣun rara nitori ṣe lajọ naa bo wọn laṣiri lasiko ti gbigba fọọmu fẹẹ wa sopin. 


Ajọ OSIEC n fesi si ọrọ kan ti ẹgbẹ APC fi sita laipẹ yii pe ajọ naa ko ni ẹka alukooro ti awọn le ko aroye awọn lọọ ba lori ohunkohun ti ajọ naa ba ṣe ti ko tẹ awọn lọrun. 


Ṣugbọn alukoro ajọ OSIEC, Sadiat Isiaka sọ ninu atejade kan pe latigba ti imurasilẹ ti bẹrẹ fun eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye loṣu keji ọdun to n bọ ni ajọ nas ti n fi eto rẹ to agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu, IPAC, leti. 


O ni koda, lati le ma jẹ ki ẹgbẹ APC ri aleebu kankan nipa eto idibo naa, fọọmu awọn oludije ọtalelugba o din mẹwaa, 250 forms, ni ajọ naa ko fun wọn lawin nigba ti wọn n rojọ pe awọn ko rowo san ni banki. 


O sọ siwaju lorukọ ajọ naa pe ko si ọrọ ifẹmusaata tabi ọrọ ibanilorukọ jẹ kankan to le di ajọ naa lọwọ lati ṣe nnkan to tọ nipa idibo naa. 


Bakan naa lo gba ẹnikẹni ti inu ba n bi niyanju lati fori le ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment