IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 4 September 2024

O ti bọ! Ko si ẹgbẹ oṣelu to le gba akoso ipinlẹ Ọṣun lọwọ PDP mọ - Ọnarebu Bisi


Ọnọrebu Sunday Bisi to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe pẹlu oniruuru iṣẹ akanṣe tijọba Gomina Adeleke ti ṣe, ko ṣee ṣe fun ẹgbẹ oṣelu miran lati gba iṣakoso lọwọ ẹgbẹ PDP. 

Lasiko to n kopa nibi eto kan ti ẹgbẹ awọn oniroyin to ti fẹyinti, League of Veteran Journalists, ṣagbekalẹ rẹ niluu Ọṣogbo lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii lo ti sọ pe awọn araalu ti dan ijọba APC ati PDP wo, wọn si ti mọ eyi to nifẹẹ wọn lọkan. 

O ni gbogbo ẹka iṣejọba, bẹrẹ lati iṣẹ akanṣe, eto ẹkọ, ironilagbara, sisan owo fawọn oṣiṣẹfẹyinti loorekoore ati lilo awọn ọmọbibi ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii kọngila ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni ọwọja iṣejọba Adeleke ti de. 

O ni latibi aṣeyọri alailoduwọn ti ẹgbẹ naa yoo ṣe lasiko idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọdun to n bọ lati araalu yoo ti mọ pe imọlẹ to n tan l'Ọṣun yoo tan kọja ọdun 2026.


Ṣugbọn nigba to n fun Sunday Bisi lesi, adari eto iroyin fun ẹgbẹ APC, Oloye Kọla Ọlabisi, sọ pe ẹnu lasan ni alaga ẹgbẹ PDP n ja. 

O ni ọdun 2026 ni ẹgbẹ naa yoo fidi rẹmi pooropo nipinlẹ Ọṣun, ti ogun wọn ko si nii gberi mọ.

No comments:

Post a Comment