Gbajugbaja akọrin ẹmi kan, Apostle Niyi Peters ti gbogbo eeyan mọ si Ẹjẹ mi, lo ti foju ba ile ejọ majistreeti kan niluu Oṣogbo lori ẹsun pe o ba olorin ẹgbẹ ẹ, Bunmi Aknnaanu, ti gbogbo eeyan mọ si Omije Oju mi, lorukọ jẹ.
Gbagedeọrọ gbọ pe Niyi Peters ko lanfaani lati ṣaṣepe beeli ti Onidajọ Ayilara fun un lọjọ Tọsidee, idi niyii ti wọn fi gbe e lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi ti wọn yoo fi yanju beeli rẹ.
Ori ẹrọ ayelujara la gbọ pe Niyi Peters ti pe Bunmi ni 'Aṣẹwo olorin', eleyii to si da wahala nla silẹ laarin awọn ololufẹ ọmọbinrin naa ati ti Niyi.
Ẹsun mẹta ni wọn fi kan Apostle Niyi Peters, wọn ni ni aago mejila ọsan ọjọ kan ninu oṣu kẹrin ọdun 2024 lo ba Bunmi lorukọ jẹ lagbegbe Oke-Odo niluu Oṣogbo nipa gbigbe fọto rẹ jade lori ikanni ayelujara, to si kọ ọ sibẹ pe 'Orin aṣẹwo' nipasẹ nọmba wasaapu rẹ.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe o n fi ohun (voice note) ranṣẹ si Bunmi pe yoo ṣegbe, ko si nii gberi mọ.
Ninu ẹsun kẹta ni wọn ti sọ pe Niyi huwa to le da wahala silẹ nipa mimọ-ọn-mọ ba orukọ olupẹjọ jẹ eleyii to lodi si ipin ikejidinlaadọrun ati ọtalelugba o din mọkanla abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lẹyin ti ọkunrin naa sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an ni agbẹjọro rẹ, Okobe Najite rọ kootu lati fun un ni beeli.
Ninu idajọ onidajọ majisreeti naa, Oluṣẹgun Ayilara, fun Niyi ni beeli pẹlu miliọnu kan naira, oṣiṣẹ ijọba meji ti ọkan lara wọn ni iwe ile lagbegbe kootu.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2024, ṣugbọn olujẹjọ ko lanfaani lati ṣaṣepe beeli rẹ, idi niyen to fi di ero Ileṣa lọjọ naa.
Iwadii fi han pe ọrẹ timọtimọ ni Ẹjẹ mi ati Omije Oju mi tẹlẹ ko too di pe ija bẹ silẹ laarin wọn, to fi di eyi ti wọn n fi ọlọpaa gbe ara wọn. Ọpọlọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ni wọn si ti da si ọrọ wahala naa ṣugbọn ti ọrọ tun bẹyin yọ lọjọọ Tọsidee ọsẹ yii.
No comments:
Post a Comment