Iya kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Arabinrin Idowu lo ti pade iku ojiji nirọlẹ ọjọ Tusidee ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan ọdun yii lagbegbe Omiloode niluu Ifẹtẹdo nipinlẹ Ọṣun.
Ile kan to ti fẹẹ wo tan tẹlẹ ladugbo naa la gbọ pe o ya lu obinrin naa, ki awọn araadugbo si to ri i fa jade labẹ alapa ile naa, o ti gbẹmi mi.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ Sifu Difẹnsi Ọṣun, Kehinde Adeleke, ṣe sọ, lasiko ti iya yii n kọja lẹgbẹ ile ọhun niṣẹlẹ buburu naa ṣẹlẹ.
Adeleke ṣalaye pe biṣẹlẹ naa ṣe ṣelẹ lawọn ajọ Sifu Difẹnsi ti sare lọ sibẹ, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
O ni awọn mọlẹbi iya naa ti sinku rẹ, bẹẹ ni amojuto to nipọn ti wa lagbegbe naa.
No comments:
Post a Comment