IROYIN YAJOYAJO

Monday, 30 September 2024

Lobatan! Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ileeṣẹ iwakusa Ṣẹgilọla pa


Latari ẹsun pe ileeṣẹ iwakusa Ṣẹgilọla to wa niluu Ileṣa ko san owo-ori, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ti ileeṣẹ naa pa. 

Kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Amofin Jimi Bada, lo gbe ẹjọ Ṣẹgilọla Resources Operating Limited lo siwaju ile ẹjọ majisreeti ilu Oṣogbo lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun yii.

Ijọba fẹsun kan ileeṣẹ naa ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba MOS/M.531/2024 pe ileeṣẹ naa ko san owo-ori to yẹ fun ijọba, bẹẹ ni ko san owo-ori awọn oṣiṣẹ rẹ lati ọdun 2019 to ti bẹrẹ iṣẹ niluu Ileṣa.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Oluṣẹgun Ayilara, gba ẹbẹ ijọba wọle, o si fun wọn laṣẹ lati ti ileeṣẹ naa pa.




No comments:

Post a Comment