IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 28 September 2024

Ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ gbena wojuu ileeṣẹ iwakusa Ṣẹgilọla


Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti fẹsun kan ileeṣẹ iwakusa kan, Segilola Gold Project, to jẹ ti Thor Explorations Ltd, ti wọn wa niluu Ileṣa lori ẹsun pe wọn ko san owo-ori, wọn n ba ayika jẹ atawọn ẹsun mi-in. 


Gẹgẹ bi oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ iwakusa atawọn nnkan alumọni, Ọjọgbọn Lukman Jimọda, ṣe ṣalaye, oniruuru awọn nnkan ti ko tọna, ti ko si yẹ keeyan maa ba lọwọ ileeṣẹ nla bii ti Ṣẹgilọla ni wọn n ṣe. 


Jimọda sọ pe awọn ileeṣẹ ti wọn wa labẹ Ṣẹgilọla Projects bii SINIC Engineering, ATF Consulting, Monurent Nigeria, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ko san ẹtọ funjọba lori awọn oṣiṣẹ wọn, ko si akọsilẹ to gun rege nipa iṣọwọṣiṣẹ wọn, bẹẹ ni wọn ko tẹle ilana aatẹle nipa amojuto awọn agbegbe ti wọn ti n ṣiṣẹ. 


O ṣalaye pe ofin latọdọ ijọba apapọ fidi rẹ mulẹ pe ijọba ipinlẹ ti ileeṣẹ iwakuda ba wa lagbara lati mọ nipa ipa ti ileeṣẹ naa yoo ko lori imugbooro eto ọrọ aje ati ayika. 


O ni lati ọdun 2019 tileeṣẹ Ṣẹgilọla ti bẹrẹ iṣẹ l'Ọṣun ni wọn ko ti tẹlẹ ofin sisan owo-ori awọn oṣiṣẹ wọn, Personal Income Tax Act ati sisan owo-ori tii ileeṣẹ, Company Income Tax Levies.  


Bakan naa lo kọminu lorii bi ileeṣẹ naa ṣe n ba awọn agbegbe ti wọn ti n wa kusa jẹ nipasẹ eefin ati asiidi to n jade latinu awọn apata ti wọn n fọ, eleyii to lewu fun ipinlẹ Ọṣun. 


Nitori idi eyi, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti pọn ọn ni dandan fun ileeṣẹ naa lati san gbogbo gbese to jẹ lati ọdun 2019 eleyii ti wọn ni o to biliọnu lọna ọgọta naira, ijọba si tun beere fun akọsilẹ finnifinni nipa iṣọwọṣiṣẹ ileeṣẹ naa


Lai ṣe bẹẹ, Jimọda sọ pe ijọba ti ṣetan lati gbe igbesẹ to tọ lati le jẹ ki ileeṣẹ naa tẹle ilana lati daabo bo ayika ati ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun. 


Ninu ọrọ tirẹ, akọṣẹmọṣẹ alanilọyẹ fun ijọba lori ọrọ iwakusa atawọn nnkan alumọọni, Dokita Wale Bọlọrunduro, sọ pe tijọba ko ba tete gbe igbesẹ lori awọn oniruuru ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Ṣẹgilọla, yoo ni ipa to pọ lori eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun. 


Bọlọrunduro ṣalaye pe ko bojumu fun iru ileeṣẹ nla bẹẹ lati kuna ninu ojuṣẹ rẹ lori owo-ori sisan. O ni nnkan itiju ni fun ileeṣẹ naa lati gbọran si ofin orileede Canada ati UK lẹnu, ṣugbọn to nira fun wọn lati ṣe bẹẹ lorileede Naijiria. 


Nigba to n dahun ibeere lori ahesọ pe idile Adeleke ni nnkan ṣe pẹlu ileeṣẹ Ṣẹgilọla, Kọmiṣanna fun eto iroyin l'Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, sọ pe irọ to jinna sootọ ni.

No comments:

Post a Comment