IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 28 September 2024

Idi ti mo fi ṣagbekalẹ iranlọwọ owo fun awọn obinrin lorukọ Oyetọla - Ọlalekan Badmus


Ọga agba ẹka eto irinna lori omi ninu ajọ to n ri si ọrọ ibudokọ ojuomi ilẹ yii, Ẹnjinia Ọlalekan Badmus, ti sọ pe oniruuru ẹkọ ti oun ri ninu igbesi aye gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, lo fa a ti oun fi pinnu lati ṣeto iranwọ owo fun awọn obinrin olokoowo kekeke. 


Nibi eto kan ti Ẹnjinia Ọlalekan ṣagbekalẹ rẹ lati ṣami ayẹyẹ ayajọ aadọrin ọdun ti Adegboyega Oyetọla de ile aye lo ti sọ pe titi lae nipinlẹ Ọṣun yoo maa ranti ọkunrin oloṣelu naa nitori pe ọgbọn-inu to ni nipa eto iṣuna ni ko jẹ ki nnkan ti daru l'Ọṣun. 


Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo nnkan to ba ta koko ninu eto iṣuna ni Oyetọla, ẹni to ti di minisita fun ọrọ irinna ati eto ọrọ-aje nileeṣẹ to n ri si ọrọ ibudokọ ori-omi bayii, maa n wa ojutu si, ko si si ipenija kankan to bori ipinlẹ Ọṣun lasiko iṣejọba rẹ gẹgẹ bii gomina. 


O ni gbogbo awọn nnkan amuyẹ yii lo fa a ti oun fi pinnu lati fi ohun manigbagbe ṣe ami ayẹyẹ ọjọọbi rẹ nipa fifun awọn obinrin ti wọn to igba (200) ni owo lati fi kun okoowo wọn. 


O ni kaakiri wọọdu to wa nijọba ibilẹ Oṣogbo lawọn ti mu awọn ti wọn janfaani eto naa, o si to miliọnu mẹwaa naira lapapọ ti awọn obinrin naa gba. 


Ẹnjinia Ọlalekan sọ siwaju pe labẹ ajọ kan ti wọn pe ni Ilerioluwa Women Empowerment and Micro Finance Programme Initiative lawọn ti gbe eto naa kalẹ. 


Nibi eto naa, to waye ni Tinubu/Shettima Campaign office niluu Osogbo, ni Badmus ti sọ pe ti eeyan ba ti le ro awọn obinrin lagbara, ohun gbogbo yoo rọrun ninu idile, wọn a si lanfaani lati ran ọkọ lọwọ. 


Alaga eto naa, Alhaji Amitolu Shittu, ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun lati mura giri, ki wọn maṣe faaye gba ede aiyede to koba wọn lọdun 2022 mọ, ki wọn mọ pe ẹgbẹ naa nikan lo le mu ayipada rere wọ ipinlẹ Ọṣun. 


Akọwe fun igbimọ to ṣeto iranwọ owo naa, Lekan Agbaje, ṣalaye pe eto naa wa lati mu idagbasoke ba awọn obinrin kaakiri wọọdu to wa nijọba ibilẹ Oṣogbo.

No comments:

Post a Comment