IROYIN YAJOYAJO

Friday, 27 September 2024

Ẹ ma parọ mọ wa o, ẹgbẹ APC kọ lo ṣokunfa wahala eto ọrọ-aje to n doju kọ Naijiria - Owoẹyẹ


Abẹnugan ana nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ti sọ pe aimọkan lo fa a ti awọn kan fi n pariwo kaakiri bayii pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lo ṣokunfa wahala eto ọrọ aje to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria bayii. 


O ni oniruuru igbesẹ ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu n gbe lọwọlọwọ to dabii pe o mu inira ba awọn araalu lo jẹ eyi to pọn dandan ki gbogbo nnkan le pada bọ sipo. 


Ọwoẹyẹ sọrọ yii niluu Oṣogbo lasiko to n yannana oniruuru eto ti wọn ti la kalẹ lati fi ṣe ayẹyẹ aadọrin ọdun ti gomina ana l'Ọṣun, to jẹ minisita fun ọrọ okoowo ori-omi bayii, Alhaji Gboyega Oyetọla, de oke eepẹ. 


O ni ọrọ Naijiria dabii amunkun ti awọn eeyan n wo pe ẹru ori rẹ wọ lai ṣakiyeai bi ẹsẹ rẹ ṣe ri. O sọ siwaju pe nnkan ti bajẹ jinna, Tinubu kan ṣe kongẹ asiko to pọn dandan lati mu atunṣe ba gbogbo rẹ ni. 


Owoẹyẹ fi da awọn araalu loju pe laipẹ laijinna ni gbogbo nnkan yoo duroore, ti yoo si ri bi olukuluku ṣe n fẹ. 


O ni odidi ọjọ marun-un lawọn yoo fi dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbesi aye Oyetọla, ẹni ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ ṣe kongẹ oriire ti ẹgbẹ APC ṣe ninu idibo gomina ipinlẹ Edo. 


Lara alakalẹ eto naa ni ipese iwosan-ọfẹ fun awọn eeyan agbegbe Oṣogbo, Iwo, Ileṣa ati Iragbiji, bakannaa ni wọn yoo si pin oniruuru ounjẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun. 


O sọ siwaju pe afojusun eeyan ẹgbẹrun kọọkan lawọn ni kaakiri agbegbe ti iwosan ọfẹ yoo ti waye ọhun, bẹẹ lawọn yoo gbe ounjẹ kaakiri ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi nipinlẹ Ọṣun.


Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, gbogbo agbegbe ti wọn ti ṣeto ilera ọfẹ naa ni wọn ti gboṣuba fun bi Alhaji Oyetọla ṣe fi eto ayẹyẹ ọjọọbi rẹ ọhun ṣeranwọ fawọn araalu. 


Bẹẹ ni wọn ke si awọn ti ori ṣẹgi ọla fun lati ṣawọkoṣe gomina ana ọhun, ki wọn ni imọlara ohun ti awọn araalu n doju kọ lasiko yii.

No comments:

Post a Comment