Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lorii bi awọn adigunjale ṣe yinbọn pa ọkunrin kan, Ọgbẹni Afọlabi Adeleke ninu ile rẹ niluu Ipetumodu nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ.
Oru ọjọ Tusidee niṣẹlẹ buburu naa ṣẹlẹ. Lẹyin ti wọn gba foonu ati owo ọwọ Adeleke atiyawo rẹ ni wọn yinbọn pa a.
Adele alukoro ileesẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Emmanuel Giwa-Alade ṣalaye pe ibọn ibilẹ ni wọn yin lu ọkunrin naa to jẹ oṣiṣẹ ni sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ nigba aye rẹ.
O ni bi awọn adigunjale naa ṣe lọ tan lawọn araadugbo fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bi awọn ọlọpaa si ṣe debẹ ni wọn gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, o ti ku.
Giwa-Alade sọ pe laipẹ ni ọwọ yoo tẹ awọn ti wọn huwa naa.
No comments:
Post a Comment