IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 September 2024

Awọn adigunjale ṣọṣẹ l'Ọṣun: Wọn yinbọn lu dẹrẹba ọkọ ero, wọn tun fipa ba obinrin kan sun

 


Lati ipinlẹ Eko lawọn eeyan inu mọto meji; bọọsi ati mọto aladani kan, ti n bọ laarọ ọjọ Wẹsidee to kọja, bi wọn si ṣe kuro niluu Ileefẹ, to ku diẹ ki wọn de Oṣu ni awọn adigunjale kan fo ja oju ọna, ti wọn si da mọto mejeeji duro.

Gẹgẹ bi ẹnikan to wa ninu mọto bọọsi naa ṣe sọ, awọn adigunjale ti wọn to mẹjọ ọhun kọkọ yinbọn lu awakọ bọọsi naa, ṣugbọn ko ku.

Bi mọto mejeeji ṣe duro ni wọn paṣẹ pe ki gbogbo awọn ero da kaadi ATM wọn jọ, wọn gba gbogbo owo ọwọ wọn, bẹẹ ni wọn paṣẹ pe ki wọn tiransifaa owo inu akanti wọn sinu akanti kan.

Nigba ti wọn n ṣe eleyii lọwọ lawọn kan lara wọn mu obinrin kan ninu mọto bọọsi naa, ti wọn si ba a lajọṣepọ nibẹ.

Diẹ lara awọn ero inu mọto ọhun ti wọn raaye sa wọnu igbo ni wọn ta awọn ti wọn wa lagbegbe naa lolobo, ti awọn ọlọpaa atawọn ọlọdẹ fi ya bo wọn, nibẹ ni ọwọ si ti tẹ ọkan lara awọn adigunjale naa.

Adele alukoro funleeṣẹ ọlọpaa Ọṣun ,Emmanuel Giwa-Alade fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni eyi ti ọwọ tẹ lara wọn ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ lori iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment