Tolulope Emmanuel, Osogbo
Okunrin eni ogbon odun kan, Oluwaseyi Ogunjinmi ti foju bale ejo majisreeti ilu Ileefe lori esun pe o dunkoko mo emi enikan, to si da wahala sile lagbegbe naa.
Seyi ni won fesun kan pe ni nnkan aago meji osan ojo karun osu kejila odun to koja lo lo sagbegbe Ijio ni Moore nilu Ileefe nibi to ti loo hale mo obinrin kan to n je Sola Awoyeye.
ASP Mathew Imepreve to n soju ileese olopa lori esun naa ni Seyi gbe aasiidi lo sile obinrin naa to si so pe oun yoo da a sii lara.
O ni wahala naa po lojo naa to je pe opelope awon ti won wa nitosi ni won tete yanju e, bi bee ko, iba da aasiidi si Arabinrin Sola lara.
O ni iwa didunkoko mo emi eeyan ati dida omi alaafia agbegbe ru ti Seyi hu ohun lodi, bee lo si nijiya nla labe abala kerindinlaadorun ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Osun n samulo re.
Agbejoro fun olujejo, Ogbeni Adewale Adegbami ro ile ejo lati faaye beeli sile fun Oluseyi pelu ileri pe ko nii salo fun igbejo nitori pe yoo fi awon oniduro ti won looko sile.
Nigba to n gbe idajo re kale, adajo majisreeti naa, Risikat Olayemi gba beeli olujejo pelu egberun lona aadota naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
O ni oniduro naa gbodo je osise ijoba to wa nipele karun to si n sise layika kootu.
Olayemi fi kun idajo re pe oniduro naa gbodo pese iwe igbanisise re pelu leta igbega to gba gbeyin lenu ise ijoba pelu kaadi idanimo eka to ti n sise.
No comments:
Post a Comment