Tolulope Emmanuel, Osogbo
Fun igba akooko leyin ogun Modakeke ati Ife, iyalenu lo je fawon ara ilu Modakeke lati ri Seneto Iyiola Omisore nibi ayeye Akoraye Day to waye lopin ose to koja.
Bo tile je pe Omisore ni se loun tele okan lara awon ti won je alaga nibi ayeye naa loun tele lo sibe, sugbon awon araalu ri igbese naa gege bii ona lati fa ojuu won mora.
Nibi ayeye Akoraye Day ikejilelogbon iru e ni Omisore ti ni ise esu ni wahala to waye laarin Modakeke ati Ife ohun je ati pe isokan ati ife ni ilu mejeeji nilo lati maa fi lo.
Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja keji lo je ori ade nibi ayeye ojo naa, tilutifon lawon araalu si fi kii kaabo sibe.
No comments:
Post a Comment