IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 3 January 2018

E ka ohun ti Feyisetan, iyawo Gomina Fayose ni yoo sele sawon alatako oko e


Arabinrin Feyisetan Fayose ti kilo gidigidi fun gbogbo awon ti won n satako oko re pe ki won jawo ninu iru igbese bee ki won ma baa ribinu Olorun.

Ninu atejade kan ni Arabinrin Fayose ti ni opo odun seyin toun n gbadura pe ki Olorun yo oselu kuro lokan oko oun ni Olorun ti so fun oun pe Oun (Olorun) nilo Fayose lorileede yii.

O ni Olorun ni ibi to ju ipinle Ekiti lo loun ti fee lo Ayodele ati pe ategun lasan lati de ibi giga yen nipinle Ekiti je, sugbon obinrin yii ni igba ati asiko loun ko mo.

Feyisetan fi kun oro re pe eni to ni ooreofe Olorun to po ni oko oun ati pe enikeni to ba n ba a forigbari kan n rojo ibinu gbigbona le ori araa re lori ni.

O kilo fun gbogbo awon ti won n wa ijakule ijoba Fayose lati jawo, bakan naa lo ni gbogbo awon ti ko fe itesiwaju ijoba rere to wa l'Ekiti bayii kan fee te ni.

Aya gomina waa gbadura fun alaafia pipe fawon eeyan ipinle Ekiti ati orileede Naijiria lapapo.


No comments:

Post a Comment