Tolulope Emmanuel, Osogbo
Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ni awon oloselu alakatakiti kan ti pinnu lati da wahala sile lodun tuntun yii nipinle Osun sugbon ijoba ko nii fojuure wo iru awon eeyan bee.
Ninu oro odun tuntun ti Aregbesola ka lojo kinni osu kinni lo ti soro naa.
Gomina ni bi alaafia se n joba nipinle Osun ko dun mo awon oloselu kan ninu, idi si niyii ti won fi n gbaradi lati lo odun idibo yii lati fi da wahala sile.
O waa ro gbogbo awon araalu lati mase yonda araa won sile gege bii ohun elo lowo awon adaluru naa.
Aregbesola ni ko si nnkan to buru ninuu kenikeni fi ehonuhan si nnkan ti ko ba te e lorun nitori alakale ijoba tiwantiwa ni sugbon eleyii ko gbodo pagidina alaafia elomiin.
O ni ojuse ijoba ni lati daabo bo emi ati dukia awon araalu, bee nijoba ko nii faaye gba ohunkohun to le da aibale aya sile fawon araalu.
No comments:
Post a Comment