Asofin to n soju awon eeyan ijoba ibile Ariwa Ife nile igbimo asofin Osun, Onorebu Tunde Olatunji ti ro gbogbo awon omo orileede yii lati mase faaye gba ohunkohun to le mu iyapa wa ninu odun 2018.
Ninu oro ikini ku odun ni Olatunji ti salaye pe ko si orileede to le dagbasoke tayo iwa awon eeyan inu e, idi niyen to fi ni iha ti awon araalu ba ko si isejoba ni yoo so aseyori isejoba naa.
Olatunji ni bi awon omo orileede Naijiria ba le fowosowopo pelu oniruuru awon adari to wa lorileede yii lowolowo, o daju pe odun yii yoo sunwon ju odun to koja lo.
Bakan naa lo ro gbogbo awon ti won wa nipo adari lorileede yii lati ni ife awon araalu lokan, ki won huwa bii eni ti yoo jabo ise iriju re lojo kan.
O ni kii se awon oloselu nikan ni won ni ojuse lati se fawon omoleyin, awon asaaju esin, awon ileese aladani ati bee bee lo naa gbodo mo pe awon omoleyin won m reti nnkan lodo won lati le mu ki orileede yii goke agba.
No comments:
Post a Comment